-
2 Sámúẹ́lì 6:3-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Àmọ́ wọ́n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ sórí kẹ̀kẹ́ tuntun,+ kí wọ́n lè fi gbé e láti ilé Ábínádábù,+ tó wà lórí òkè; Úsà àti Áhíò, àwọn ọmọ Ábínádábù, sì ń darí kẹ̀kẹ́ tuntun náà.
4 Nítorí náà, wọ́n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ láti ilé Ábínádábù tó wà lórí òkè, Áhíò sì ń rìn lọ níwájú Àpótí náà. 5 Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì ń ṣe ayẹyẹ níwájú Jèhófà pẹ̀lú onírúurú ohun ìkọrin tí a fi igi júnípà ṣe pẹ̀lú háàpù àti àwọn ohun ìkọrin míì tó ní okùn tín-ín-rín+ àti ìlù tanboríìnì+ àti sítírọ́mù pẹ̀lú síńbálì.*+ 6 Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ibi ìpakà Nákónì, Úsà na ọwọ́ rẹ̀ kí ó lè gbá Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ mú,+ torí màlúù náà mú kí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dojú dé. 7 Ni ìbínú Jèhófà bá ru sí Úsà, Ọlọ́run tòótọ́ pa á + níbẹ̀ nítorí ìwà àìlọ́wọ̀+ tí ó hù, ó sì kú síbẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ Àpótí Ọlọ́run tòótọ́. 8 Àmọ́ inú bí Dáfídì* nítorí pé ìbínú Jèhófà ru sí Úsà; wọ́n sì wá ń pe ibẹ̀ ní Peresi-úsà* títí di òní yìí.
-