-
2 Sámúẹ́lì 6:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Nítorí náà, wọ́n gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ láti ilé Ábínádábù tó wà lórí òkè, Áhíò sì ń rìn lọ níwájú Àpótí náà. 5 Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì ń ṣe ayẹyẹ níwájú Jèhófà pẹ̀lú onírúurú ohun ìkọrin tí a fi igi júnípà ṣe pẹ̀lú háàpù àti àwọn ohun ìkọrin míì tó ní okùn tín-ín-rín+ àti ìlù tanboríìnì+ àti sítírọ́mù pẹ̀lú síńbálì.*+
-
-
2 Sámúẹ́lì 6:12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Wọ́n ròyìn fún Ọba Dáfídì pé: “Jèhófà ti bù kún ilé Obedi-édómù àti gbogbo ohun ìní rẹ̀ nítorí Àpótí Ọlọ́run tòótọ́.” Torí náà, tayọ̀tayọ̀+ ni Dáfídì lọ gbé Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ láti ilé Obedi-édómù wá sí Ìlú Dáfídì.
-