-
2 Sámúẹ́lì 24:24, 25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Àmọ́ ọba sọ fún Áráúnà pé: “Rárá o, mo gbọ́dọ̀ rà á lọ́wọ́ rẹ ní iye kan. Mi ò ní rú ẹbọ sísun tí kò ná mi ní nǹkan kan sí Jèhófà Ọlọ́run mi.” Ni Dáfídì bá ra ibi ìpakà náà àti màlúù náà ní àádọ́ta (50) ṣékélì fàdákà.*+ 25 Dáfídì mọ pẹpẹ+ kan síbẹ̀ fún Jèhófà, ó sì rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀. Lẹ́yìn náà, Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ilẹ̀ náà,+ àjàkálẹ̀ àrùn tó ń pa àwọn èèyàn Ísírẹ́lì sì dáwọ́ dúró.
-