-
1 Kíróníkà 29:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Nítorí náà, àwọn olórí àwọn agbo ilé, àwọn olórí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ti ọgọ́rọ̀ọ̀rún+ pẹ̀lú àwọn olórí tó ń bójú tó iṣẹ́ ọba+ jáde wá tinú-tinú. 7 Àwọn nǹkan tí wọ́n fi sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́ nìyí: ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) tálẹ́ńtì wúrà, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) owó dáríkì,* ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ńtì fàdákà, ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) tálẹ́ńtì bàbà àti ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) tálẹ́ńtì irin.
-