-
Jẹ́nẹ́sísì 38:2-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Ibẹ̀ ni Júdà ti rí ọmọbìnrin ara Kénáánì+ kan tó ń jẹ́ Ṣúà. Ó mú un, ó bá a lò pọ̀, 3 ó sì lóyún. Lẹ́yìn náà, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Éérì.+ 4 Ó tún lóyún, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ónánì. 5 Ó tún bí ọmọkùnrin míì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ṣélà. Ìlú Ákísíbù+ ni ó* wà nígbà tí obìnrin náà bí i.
-