-
Ẹ́kísódù 18:25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Mósè yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n nínú gbogbo Ísírẹ́lì, ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn èèyàn náà, ó fi wọ́n ṣe olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta àti olórí àwọn mẹ́wàá-mẹ́wàá.
-
-
1 Sámúẹ́lì 8:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ó ní: “Ohun tí ọba tó bá jẹ lórí yín máa lẹ́tọ̀ọ́ láti gbà nìyí:+ Á mú àwọn ọmọkùnrin yín,+ á sì fi wọ́n sínú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀,+ á wá sọ wọ́n di agẹṣin rẹ̀,+ àwọn kan á sì ní láti máa sáré níwájú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀. 12 Á yan àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún+ àti àwọn olórí àràádọ́ta+ fún ara rẹ̀, àwọn kan á máa bá a túlẹ̀,+ wọ́n á máa bá a kórè,+ wọ́n á sì máa ṣe ohun ìjà fún un àti àwọn ohun èlò kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀.+
-