-
Diutarónómì 4:19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Tí o bá wá yíjú sókè wo ọ̀run, tí o sì rí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀, gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, o ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọkàn rẹ fà sí wọn débi pé o máa forí balẹ̀ fún wọn, tí o sì máa sìn wọ́n.+ Gbogbo èèyàn lábẹ́ ọ̀run ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ fi wọ́n fún.
-
-
2 Àwọn Ọba 23:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ó lé àwọn àlùfáà ọlọ́run ilẹ̀ àjèjì kúrò lẹ́nu iṣẹ́, àwọn tí ọba Júdà yàn láti máa mú ẹbọ rú èéfín lórí àwọn ibi gíga ní àwọn ìlú Júdà àti ní àyíká Jerúsálẹ́mù títí kan àwọn tó ń mú ẹbọ rú èéfín sí Báálì, sí oòrùn àti sí òṣùpá àti sí àwọn àgbájọ ìràwọ̀ sódíákì àti sí gbogbo ọmọ ogun ọ̀run.+
-