3 Ó tún àwọn ibi gíga kọ́, èyí tí Hẹsikáyà bàbá rẹ̀ pa run,+ ó mọ àwọn pẹpẹ fún Báálì, ó sì ṣe òpó òrìṣà,*+ bí Áhábù ọba Ísírẹ́lì ti ṣe.+ Ó forí balẹ̀ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.+
7 Ó gbé ère òpó òrìṣà*+ tó gbẹ́ wá sínú ilé tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ fún Dáfídì àti Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Inú ilé yìí àti ní Jerúsálẹ́mù, tí mo ti yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ni màá fi orúkọ mi sí títí láé.+