3 Ó tún àwọn ibi gíga kọ́, èyí tí Hẹsikáyà bàbá rẹ̀ pa run,+ ó mọ àwọn pẹpẹ fún Báálì, ó sì ṣe òpó òrìṣà,*+ bí Áhábù ọba Ísírẹ́lì ti ṣe.+ Ó forí balẹ̀ fún gbogbo ọmọ ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.+
6 Ó sun ọmọ rẹ̀ nínú iná; ó ń pidán, ó ń woṣẹ́,+ ó sì yan àwọn abẹ́mìílò àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́.+ Ohun búburú tó pọ̀ gan-an ló ṣe lójú Jèhófà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un bínú.
28Ẹni ogún (20) ọdún ni Áhásì+ nígbà tó jọba, ọdún mẹ́rìndínlógún (16) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Kò ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+
3 Yàtọ̀ síyẹn, ó mú ẹbọ rú èéfín ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,* ó sì sun àwọn ọmọ rẹ̀ nínú iná,+ ó tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ohun ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè+ tí Jèhófà lé kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe.