-
Jeremáyà 27:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ẹ má fetí sí wọn. Ẹ sin ọba Bábílónì kí ẹ sì máa wà láàyè.+ Kí ló dé tí ìlú yìí fi máa di àwókù? 18 Àmọ́ tó bá jẹ́ pé wòlíì ni wọ́n, tí ọ̀rọ̀ Jèhófà sì wà lẹ́nu wọn, ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí wọ́n bẹ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, pé kí wọ́n má ṣe kó àwọn nǹkan èlò tó ṣẹ́ kù ní ilé Jèhófà àti ní ilé* ọba Júdà àti ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.’
-