-
2 Àwọn Ọba 24:18-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) ni Sedekáyà nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútálì+ ọmọ Jeremáyà láti Líbínà. 19 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, gbogbo ohun tí Jèhóákímù ṣe ni òun náà ṣe.+ 20 Ìbínú Jèhófà ló mú kí àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù àti ní Júdà, títí ó fi gbá wọn dà nù kúrò níwájú rẹ̀.+ Sedekáyà sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì.+
-
-
Jeremáyà 52:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
52 Ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) ni Sedekáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlá (11) ló sì fi jọba ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hámútálì+ ọmọ Jeremáyà ará Líbínà. 2 Ó sì ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, gbogbo ohun tí Jèhóákímù ṣe ni òun náà ṣe.+ 3 Ìbínú Jèhófà ló mú kí àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù àti ní Júdà, títí ó fi gbá wọn dà nù kúrò níwájú rẹ̀.+ Sedekáyà sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì.+
-