-
1 Àwọn Ọba 8:31, 32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
31 “Nígbà tí ẹnì kan bá ṣẹ ọmọnìkejì rẹ̀, tó mú kó búra,* tó sì mú kó wà lábẹ́ ìbúra* náà, tó bá wá síwájú pẹpẹ rẹ nínú ilé yìí nígbà tó ṣì wà lábẹ́ ìbúra* náà,+ 32 nígbà náà, kí o gbọ́ láti ọ̀run, kí o gbé ìgbésẹ̀, kí o sì ṣe ìdájọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ, kí o pe ẹni burúkú ní ẹlẹ́bi,* kí o sì jẹ́ kí ohun tó ṣe dà lé e lórí, kí o pe olódodo ní aláìṣẹ̀,* kí o sì san èrè òdodo rẹ̀ fún un.+
-