-
2 Kíróníkà 8:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ó tún kọ́ Bẹti-hórónì Òkè+ àti Bẹti-hórónì Ìsàlẹ̀,+ àwọn ìlú aláàbò tó ní ògiri àti àwọn ẹnubodè pẹ̀lú ọ̀pá ìdábùú. 6 Bákan náà, ó kọ́ Báálátì+ pẹ̀lú gbogbo àwọn ìlú tó ń kó nǹkan pa mọ́ sí, gbogbo àwọn ìlú kẹ̀kẹ́ ẹṣin,+ àwọn ìlú àwọn agẹṣin àti ohunkóhun tó wu Sólómọ́nì láti kọ́ sí Jerúsálẹ́mù, sí Lẹ́bánónì àti sí gbogbo ilẹ̀ tó ń ṣàkóso lé lórí.
-