-
1 Kíróníkà 25:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Àwọn pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn tí a ti kọ́ níṣẹ́ orin láti máa kọrin sí Jèhófà jẹ́ igba ó lé ọgọ́rin àti mẹ́jọ (288), gbogbo wọn jẹ́ ọ̀jáfáfá.
-
-
2 Kíróníkà 5:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Nígbà tí àwọn àlùfáà jáde láti ibi mímọ́ (nítorí gbogbo àwọn àlùfáà tó wà níbẹ̀ ni wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́,+ láìka àwùjọ tí wọ́n wà sí),+ 12 gbogbo àwọn ọmọ Léfì tó jẹ́ akọrin+ tí wọ́n jẹ́ ti Ásáfù,+ ti Hémánì,+ ti Jédútúnì + àti ti àwọn ọmọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn ló wọ aṣọ àtàtà, síńbálì* wà lọ́wọ́ wọn àti àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù; wọ́n dúró sí apá ìlà oòrùn pẹpẹ, àwọn pẹ̀lú ọgọ́fà (120) àlùfáà tó ń fun kàkàkí.+
-