-
1 Àwọn Ọba 10:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Gbogbo ohun èlò tí Ọba Sólómọ́nì fi ń mu nǹkan jẹ́ wúrà, gbogbo ohun èlò Ilé Igbó Lẹ́bánónì+ sì jẹ́ ògidì wúrà. Kò sí ìkankan tí wọ́n fi fàdákà ṣe, nítorí fàdákà kò já mọ́ nǹkan kan nígbà ayé Sólómọ́nì.+ 22 Ọba ní ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun Táṣíṣì+ lórí òkun pẹ̀lú ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun ti Hírámù. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún mẹ́ta ni ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun Táṣíṣì máa ń kó wúrà àti fàdákà, eyín erin,+ àwọn ìnàkí àti àwọn ẹyẹ ọ̀kín wọlé.
-
-
1 Àwọn Ọba 10:27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Ọba mú kí fàdákà tó wà ní Jerúsálẹ́mù pọ̀ rẹpẹtẹ bí òkúta, ó sì mú kí igi kédárì pọ̀ rẹpẹtẹ bí àwọn igi síkámórè tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là.+
-