-
1 Àwọn Ọba 11:30, 31Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Áhíjà di ẹ̀wù tuntun tó wà lọ́rùn rẹ̀ mú, ó sì fà á ya sí ọ̀nà méjìlá (12). 31 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Jèróbóámù pé:
“Gba mẹ́wàá yìí, torí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Wò ó, màá fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Sólómọ́nì, màá sì fún ọ ní ẹ̀yà mẹ́wàá.+
-
-
1 Àwọn Ọba 14:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Torí náà, Jèróbóámù sọ fún ìyàwó rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, dìde, yí ìmúra rẹ pa dà kí wọ́n má bàa mọ̀ pé ìyàwó Jèróbóámù ni ọ́, kí o sì lọ sí Ṣílò. Wò ó! Wòlíì Áhíjà wà níbẹ̀. Òun ni ó sọ nípa mi pé màá di ọba lórí àwọn èèyàn yìí.+
-
-
1 Àwọn Ọba 14:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Bí Áhíjà ṣe gbọ́ ìró ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó ń bọ̀ lẹ́nu ọ̀nà, ó sọ pé: “Wọlé, ìyàwó Jèróbóámù. Kí ló dé tí o fi ṣe bíi pé ẹlòmíràn ni ọ́? Iṣẹ́ tó lágbára kan wà tí Ọlọ́run ní kí n jẹ́ fún ọ.
-