21 Ní àkókò yẹn, Rèhóbóámù ọmọ Sólómọ́nì ti di ọba ní Júdà. Ẹni ọdún mọ́kànlélógójì (41) ni Rèhóbóámù nígbà tó di ọba, ó sì fi ọdún mẹ́tàdínlógún (17) jọba ní Jerúsálẹ́mù, ìlú tí Jèhófà yàn+ nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ sí.+ Orúkọ ìyá Rèhóbóámù ni Náámà, ọmọ Ámónì+ sì ni.