30 Ìgbà gbogbo ni ogun ń wáyé láàárín Rèhóbóámù àti Jèróbóámù.+ 31 Níkẹyìn, Rèhóbóámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀ ní Ìlú Dáfídì.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Náámà, ọmọ Ámónì+ sì ni. Ábíjámù+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.