17 Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n fọ́ àwọn òkúta ńláńlá, àwọn òkúta iyebíye,+ kí wọ́n lè fi òkúta tí wọ́n bá gbẹ́+ ṣe ìpìlẹ̀ ilé+ náà. 18 Torí náà, àwọn kọ́lékọ́lé Sólómọ́nì àti ti Hírámù pẹ̀lú àwọn ará Gébálì+ gé àwọn òkúta náà, wọ́n sì ṣètò àwọn gẹdú àti àwọn òkúta tí wọ́n máa fi kọ́ ilé náà.