14 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Kọ ọ̀rọ̀ yìí sínú ìwé fún ìrántí, kí o sì tún un sọ fún Jóṣúà pé, ‘Màá mú kí wọ́n gbàgbé Ámálékì pátápátá lábẹ́ ọ̀run.’”+15 Mósè mọ pẹpẹ kan, ó sì sọ ọ́ ní Jèhófà-nisì,*
12 Ìgbà náà ni Sámúẹ́lì gbé òkúta kan,+ ó sì gbé e kalẹ̀ sí àárín Mísípà àti Jẹ́ṣánà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ẹbinísà* torí ó sọ pé: “Jèhófà ti ń ràn wá lọ́wọ́ títí di ìsinsìnyí.”+