-
2 Àwọn Ọba 8:20-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Nígbà ayé rẹ̀, Édómù ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà,+ wọ́n sì fi ọba jẹ lórí ara wọn.+ 21 Nítorí náà, Jèhórámù sọdá lọ sọ́dọ̀ Sáírì pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, ó dìde ní òru, ó sì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Édómù tí wọ́n yí i ká àti àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin; àwọn ọmọ ogun náà sì sá lọ sínú àgọ́ wọn. 22 Àmọ́ Édómù ṣì ń ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà títí di òní yìí. Líbínà+ pẹ̀lú ṣọ̀tẹ̀ ní àkókò yẹn.
-