-
2 Kíróníkà 24:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé* Sekaráyà ọmọ àlùfáà Jèhóádà,+ ó dúró sórí ibi tó ga láàárín àwọn èèyàn náà, ó sì sọ fún wọn pé: “Ohun tí Ọlọ́run tòótọ́ sọ nìyí, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń tẹ àwọn àṣẹ Jèhófà lójú? Ẹ ò ní ṣàṣeyọrí! Nítorí ẹ ti fi Jèhófà sílẹ̀, òun náà á sì fi yín sílẹ̀.’”+ 21 Àmọ́ wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọn,+ wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, ní àgbàlá ilé Jèhófà.+
-