-
Léfítíkù 13:45, 46Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
45 Ní ti adẹ́tẹ̀ tó ní àrùn náà, kó wọ aṣọ tó ti fà ya, kó má sì tọ́jú irun orí rẹ̀, kó bo irunmú rẹ̀, kó máa ké jáde pé, ‘Aláìmọ́, aláìmọ́!’ 46 Gbogbo ọjọ́ tí àrùn náà bá fi wà lára rẹ̀ ni yóò fi jẹ́ aláìmọ́. Kó lọ máa dá gbé torí pé aláìmọ́ ni. Ẹ̀yìn ibùdó ni kó máa gbé.+
-
-
Nọ́ńbà 12:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Jèhófà dá Mósè lóhùn pé: “Tó bá jẹ́ bàbá rẹ̀ ló tutọ́ sí i lójú, ǹjẹ́ ọjọ́ méje kọ́ lojú fi máa tì í? Ẹ lọ sé e mọ́ ẹ̀yìn ibùdó+ fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn náà, kí ẹ jẹ́ kó wọlé.” 15 Torí náà, wọ́n sé Míríámù mọ́ ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje,+ àwọn èèyàn náà ò sì tú àgọ́ wọn ká títí Míríámù fi pa dà wọlé.
-