-
1 Kíróníkà 15:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Yàtọ̀ síyẹn, Dáfídì pe àlùfáà Sádókù+ àti àlùfáà Ábíátárì+ àti àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn Úríélì, Ásáyà, Jóẹ́lì, Ṣemáyà, Élíélì àti Ámínádábù, 12 ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ni olórí agbo ilé àwọn ọmọ Léfì. Ẹ ya ara yín sí mímọ́, ẹ̀yin àti àwọn arákùnrin yín, kí ẹ sì gbé Àpótí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wá sí ibi tí mo ti ṣètò sílẹ̀ fún un.
-