-
2 Àwọn Ọba 24:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Bó ṣe mú Jèhóákínì+ lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì+ nìyẹn; ó tún mú ìyá ọba, àwọn ìyàwó ọba, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àti àwọn aṣáájú ilẹ̀ náà, ó sì kó wọn ní ìgbèkùn láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì. 16 Ọba Bábílónì tún kó gbogbo àwọn jagunjagun lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì, ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ni wọ́n àti ẹgbẹ̀rún kan (1,000) àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn oníṣẹ́ irin,* alágbára ni gbogbo wọn, wọ́n sì ti kọ́ iṣẹ́ ogun.
-
-
2 Àwọn Ọba 25:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn tó wà ní ìlú náà lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì àti àwọn tó sá wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó kù.+
-