3 Ní àkókò yẹn, Táténáì gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò àti Ṣetari-bósénáì pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn wá bá wọn, wọ́n sì bi wọ́n pé: “Ta ló fún yín láṣẹ láti kọ́ ilé yìí, kí ẹ sì parí iṣẹ́ rẹ̀?” 4 Wọ́n wá béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Kí lorúkọ àwọn ọkùnrin tó ń kọ́ ilé yìí?”