12 “Atasásítà,+ ọba àwọn ọba, sí àlùfáà Ẹ́sírà, adàwékọ Òfin Ọlọ́run ọ̀run: Kí àlàáfíà pípé máa jẹ́ tìrẹ. Ní báyìí, 13 mo ti pàṣẹ kan pé kí gbogbo ẹni tó wà lábẹ́ àkóso mi tó jẹ́ ara àwọn èèyàn Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà wọn àti àwọn ọmọ Léfì, tó bá fẹ́ bá ọ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí ó bá ọ lọ.+