28 Ó ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi níwájú ọba+ àti àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀+ àti níwájú gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí wọ́n jẹ́ alágbára. Torí náà, mo mọ́kàn le nítorí ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run mi wà lára mi, mo sì kó àwọn aṣáájú ọkùnrin jọ látinú Ísírẹ́lì kí wọ́n lè bá mi lọ.