29 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá pa àwọn orílẹ̀-èdè tí o máa lé kúrò run,+ tí o sì wá ń gbé ilẹ̀ wọn, 30 rí i pé o ò kó sí ìdẹkùn lẹ́yìn tí wọ́n bá pa run kúrò níwájú rẹ. Má ṣe béèrè nípa àwọn ọlọ́run wọn pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè yìí ṣe máa ń sin àwọn ọlọ́run wọn? Ohun tí wọ́n ṣe lèmi náà máa ṣe.’+