-
Ẹ́sírà 9:5, 6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Nígbà tí àkókò ọrẹ ọkà ìrọ̀lẹ́+ tó, mo dìde nínú ìtìjú tó bá mi, tèmi ti ẹ̀wù mi àti aṣọ àwọ̀lékè mi tí kò lápá tó ti ya, mo kúnlẹ̀, mo sì tẹ́ ọwọ́ mi sí Jèhófà Ọlọ́run mi. 6 Mo sọ pé: “Ìwọ Ọlọ́run mi, ojú ń tì mí, ara sì ń tì mí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, ìwọ Ọlọ́run mi, nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ti pọ̀ gan-an lórí wa, ẹ̀bi wa sì ti ga dé ọ̀run.+
-