-
Diutarónómì 31:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Mósè pàṣẹ fún wọn pé: “Ní òpin ọdún méje-méje, ní àkókò rẹ̀ nígbà ọdún ìtúsílẹ̀,+ ní àkókò Àjọyọ̀ Àtíbàbà,+ 11 nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì bá wá síwájú Jèhófà+ Ọlọ́run rẹ ní ibi tó yàn, kí ẹ ka Òfin yìí sí gbogbo Ísírẹ́lì létí.+ 12 Ẹ kó àwọn èèyàn náà jọ,+ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé* àti àwọn àjèjì yín tó ń gbé nínú àwọn ìlú* yín, kí wọ́n lè fetí sílẹ̀, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run yín, kí wọ́n máa bẹ̀rù rẹ̀, kí wọ́n sì lè máa rí i dájú pé àwọn ń tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí.
-