14 Nígbà tí ìrì náà gbẹ, ohun kan wà lórí ilẹ̀ ní aginjù náà tó rí wínníwínní.+ Ó rí bíi yìnyín tó rọ̀ sórí ilẹ̀. 15 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i, wọ́n ń bi ara wọn pé, “Kí nìyí?” torí wọn ò mọ ohun tó jẹ́. Mósè sọ fún wọn pé: “Oúnjẹ tí Jèhófà fún yín pé kí ẹ jẹ ni.+