3 Ọba dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpó, ó sì dá májẹ̀mú níwájú Jèhófà+ pé gbogbo ọkàn àti gbogbo ara ni òun á máa fi tẹ̀ lé Jèhófà, òun á sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn ìránnilétí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀, láti máa ṣe ohun tí májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé yìí sọ. Gbogbo àwọn èèyàn náà sì fara mọ́ májẹ̀mú náà.+