4 Lẹ́yìn náà, ó yan lára àwọn ọmọ Léfì láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú Àpótí Jèhófà,+ kí wọ́n máa bọlá fún* Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kí wọ́n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, kí wọ́n sì máa yìn ín.
28 Iṣẹ́ wọn ni láti máa ran àwọn ọmọ Áárónì+ lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà, kí wọ́n máa bójú tó àwọn àgbàlá,+ àwọn yàrá ìjẹun, mímú kí gbogbo ohun mímọ́ wà ní mímọ́ àti iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yọjú nínú iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run tòótọ́.