36 Àwọn ọmọbìnrin Lọ́ọ̀tì méjèèjì lóyún nípasẹ̀ bàbá wọn. 37 Èyí àkọ́bí bí ọmọkùnrin kan, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Móábù.+ Òun ló wá di bàbá àwọn ọmọ Móábù.+ 38 Èyí àbúrò náà bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹni-ámì. Òun ló wá di bàbá àwọn ọmọ Ámónì.+