-
Nehemáyà 10:38, 39Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
38 Kí àlùfáà, ọmọ Áárónì, wà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì nígbà tí àwọn ọmọ Léfì bá ń gba ìdá mẹ́wàá; kí àwọn ọmọ Léfì mú ìdá mẹ́wàá lára ìdá mẹ́wàá ti ilé Ọlọ́run wa,+ kí wọ́n sì kó o sí àwọn yàrá* tó wà ní ilé ìkẹ́rùsí. 39 Inú àwọn yàrá tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí* ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn ọmọ Léfì máa mú ọrẹ+ ọkà, wáìnì tuntun àti òróró wá,+ ibẹ̀ sì ni kí àwọn nǹkan èlò ibi mímọ́ máa wà títí kan àwọn àlùfáà tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn àti àwọn aṣọ́bodè pẹ̀lú àwọn akọrin. A kò sì ní pa ilé Ọlọ́run wa tì.+
-