-
Ẹ́sítà 9:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Ó sọ fún wọn pé kí wọ́n máa pa ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Ádárì àti ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù náà mọ́ lọ́dọọdún, 22 torí ní àwọn ọjọ́ yẹn, àwọn Júù sinmi kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, oṣù yẹn ni ìbànújẹ́ wọn di ayọ̀, tí ọ̀fọ̀+ wọn sì di àjọyọ̀. Ó ní kí wọ́n máa fi àwọn ọjọ́ náà ṣe ọjọ́ àsè àti ọjọ́ ayọ̀ àti àkókò láti fi oúnjẹ ránṣẹ́ sí ara wọn àti láti máa fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí àwọn aláìní.
-