-
Ẹ́sítà 3:8, 9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Hámánì wá sọ fún Ọba Ahasuérúsì pé: “Àwọn èèyàn kan wà káàkiri tí wọ́n ń dá tiwọn ṣe láàárín àwọn èèyàn+ tó wà ní gbogbo ìpínlẹ̀* tó wà lábẹ́ àkóso rẹ,+ òfin wọn yàtọ̀ sí ti gbogbo àwọn èèyàn yòókù; wọn kì í sì í pa òfin ọba mọ́, wọ́n á pa ọba lára tí a bá fi wọ́n sílẹ̀ bẹ́ẹ̀. 9 Tó bá dáa lójú ọba, kí ó pa àṣẹ kan, kí wọ́n sì kọ ọ́ sílẹ̀ pé kí a pa wọ́n run. Màá fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ńtì* fàdákà pé kí wọ́n kó o sínú ibi ìṣúra ọba.”*
-