-
Ẹ́sítà 5:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Torí náà, Séréṣì aya rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Jẹ́ kí wọ́n gbé òpó igi kan nàró, kí ó ga ní àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́.* Tó bá di àárọ̀, sọ fún ọba pé kí wọ́n gbé Módékáì kọ́ sórí rẹ̀.+ Lẹ́yìn náà, kí o bá ọba lọ gbádùn ara rẹ níbi àsè náà.” Àbá yìí dára lójú Hámánì, torí náà ó ní kí wọ́n gbé òpó igi kan nàró.
-
-
Ẹ́sítà 7:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Torí náà, wọ́n gbé Hámánì kọ́ sórí òpó igi tó ṣe fún Módékáì, ìbínú ọba sì rọlẹ̀.
-
-
Ẹ́sítà 9:14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Torí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n ṣe òfin kan ní Ṣúṣánì,* wọ́n sì gbé àwọn ọmọkùnrin Hámánì mẹ́wẹ̀ẹ̀wá kọ́.
-