-
Ẹ́sítà 2:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Kí ọba yan àwọn kọmíṣọ́nnà ní gbogbo ìpínlẹ̀* tó wà lábẹ́ àkóso rẹ̀+ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó jẹ́ wúńdíá arẹwà jọ sí Ṣúṣánì* ilé ńlá,* ní ilé àwọn obìnrin.* Kí a fi wọ́n sábẹ́ àbójútó Hégáì+ ìwẹ̀fà ọba, olùtọ́jú àwọn obìnrin, kí wọ́n sì máa gba ìtọ́jú aṣaralóge.* 4 Ọ̀dọ́bìnrin tó bá wu ọba jù lọ ló máa di ayaba dípò Fáṣítì.”+ Àbá náà dára lójú ọba, ohun tó sì ṣe nìyẹn.
-