14 Nígbà náà, Ábúsálómù àti gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì sọ pé: “Ìmọ̀ràn Húṣáì ará Áríkì dára ju+ ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì!” Nítorí Jèhófà ti pinnu* láti sọ ìmọ̀ràn rere Áhítófẹ́lì+ di asán, kí Jèhófà lè mú àjálù bá Ábúsálómù.+
25 Nígbà náà, Jésù sọ pé: “Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, mo yìn ọ́ ní gbangba, torí pé o fi àwọn nǹkan yìí pa mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ọmọdé.+