-
Jóòbù 10:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Torí náà, kí ló dé tí o mú mi jáde látinú ikùn?+
Ó yẹ kí n ti kú kí ojú kankan tó rí mi.
19 Ṣe ni ì bá dà bíi pé mi ò gbé ayé rí;
Mi ò bá kàn ti inú ikùn lọ sí sàréè.’
-
-
Jeremáyà 15:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ìwọ ìyá mi, mo gbé nítorí pé o bí mi,+
Ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ náà ń bá jà, tí wọ́n sì ń bá fa wàhálà.
Mi ò yáni lówó, bẹ́ẹ̀ ni mi ò yáwó lọ́wọ́ ẹnì kankan;
Àmọ́ gbogbo wọn ń gbé mi ṣépè.
-