-
Jẹ́nẹ́sísì 38:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Àmọ́, ní nǹkan bí oṣù mẹ́ta lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n sọ fún Júdà pé: “Támárì ìyàwó ọmọ rẹ ṣe aṣẹ́wó, ó sì ti lóyún nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ṣe.” Ni Júdà bá sọ pé: “Ẹ mú un jáde ká sì sun ún.”+
-
-
Léfítíkù 20:10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá ìyàwó ọkùnrin míì ṣe àgbèrè: Ẹ gbọ́dọ̀ pa ẹni tó bá ìyàwó ẹnì kejì rẹ̀ ṣe àgbèrè, ọkùnrin alágbèrè àti obìnrin alágbèrè náà.+
-
-
Diutarónómì 22:22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 “Tí ẹ bá rí ọkùnrin kan tó bá obìnrin tó jẹ́ ìyàwó ẹlòmíì sùn, ṣe ni kí ẹ pa àwọn méjèèjì, ọkùnrin tó bá obìnrin náà sùn pẹ̀lú obìnrin yẹn.+ Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò ní Ísírẹ́lì.
-