12 “Èmi fúnra mi ni Ẹni tó ń tù yín nínú.+
Ṣé ó wá yẹ kí ẹ máa bẹ̀rù ẹni kíkú tó máa kú+
Àti ọmọ aráyé tó máa rọ bíi koríko tútù?
13 Kí ló dé tí o gbàgbé Jèhófà Aṣẹ̀dá rẹ,+
Ẹni tó na ọ̀run,+ tó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?
Ò ń bẹ̀rù ìbínú aninilára ṣáá láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,
Àfi bíi pé ó láṣẹ láti pa ọ́ run.
Ibo wá ni ìbínú aninilára wà?