6 Jèhófà wá sọ fún Sátánì pé: “Wò ó! Ó wà ní ọwọ́ rẹ!* Àmọ́, o ò gbọ́dọ̀ gba ẹ̀mí* rẹ̀!” 7 Ni Sátánì bá jáde kúrò níwájú* Jèhófà, ó sì fi eéwo tó ń roni lára*+ kọ lu Jóòbù láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀.
11 Ẹ wò ó! A ka àwọn tó ní ìfaradà sí aláyọ̀.*+ Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù,+ ẹ sì ti rí ibi tí Jèhófà* jẹ́ kó yọrí sí,+ pé Jèhófà* ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó pọ̀ gan-an,* ó sì jẹ́ aláàánú.+