3 Ẹran ọ̀sìn rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje (7,000) àgùntàn, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ràkúnmí, ẹgbẹ̀rún kan (1,000) màlúù àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó tún ní àwọn ìránṣẹ́ tó pọ̀ gan-an débi pé òun ló wá lọ́lá jù lọ nínú gbogbo àwọn ará Ìlà Oòrùn.