-
Sáàmù 108:2-5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Jí, ìwọ ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín; àti ìwọ náà, háàpù.+
Màá jí ní kùtùkùtù.
3 Jèhófà, màá yìn ọ́ láàárín àwọn èèyàn,
Màá sì fi orin yìn ọ́* láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.
4 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga gan-an, ó dé ọ̀run,+
Òtítọ́ rẹ sì ga dé sánmà.
5 Gbé ara rẹ ga ju ọ̀run lọ, ìwọ Ọlọ́run;
Kí ògo rẹ wà lórí gbogbo ayé.+
-