-
Jeremáyà 17:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 Ohun tí Jèhófà sọ fún mi nìyí: “Lọ, kí o sì dúró ní ẹnubodè àwọn ọmọ èèyàn náà, èyí tí àwọn ọba Júdà ń gbà wọlé, tí wọ́n sì ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.+ 20 Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin ọba Júdà àti gbogbo ẹ̀yin èèyàn Júdà pẹ̀lú gbogbo ẹ̀yin tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, tí ẹ̀ ń gba àwọn ẹnubodè yìí wọlé.
-