-
Jóòbù 34:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Torí ó máa fi ohun tí èèyàn bá ṣe san án lẹ́san,+
Ó sì máa mú kó jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
-
-
Róòmù 2:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Yóò san kálukú lẹ́san gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀:+
-
-
Ìfihàn 20:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Mo rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, wọ́n dúró síwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Àmọ́ a ṣí àkájọ ìwé míì; àkájọ ìwé ìyè ni.+ A fi àwọn ohun tí a kọ sínú àkájọ ìwé náà ṣèdájọ́ àwọn òkú bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.+ 13 Òkun yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú rẹ̀, ikú àti Isà Òkú* yọ̀ǹda àwọn òkú tó wà nínú wọn, a sì ṣèdájọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn ṣe rí.+
-