23 kìkì pé kí ẹ dúró nínú ìgbàgbọ́,+ kí ẹ fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà,+ kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin,+ kí ẹ má yà kúrò nínú ìrètí ìhìn rere tí ẹ gbọ́, tí a sì ti wàásù láàárín gbogbo ẹ̀dá tó wà lábẹ́ ọ̀run.+ Torí ìhìn rere yìí la ṣe yan èmi Pọ́ọ̀lù láti di òjíṣẹ́.+